Asojú Adarí Ìgbìmọ̀ àti Adarí ológun (Ag HoM/FC) ti Ọmọ ogun ààbò Abyei fìdíhẹẹ́ fún Àjọ ìṣọ̀kan (UNISFA), Ajagun Benjamin Sawyer gbóríyìnti fún ìmọṣẹ́, ìfarasisẹ́, àti ìsiṣẹ́ lọ́nà tó tọ́ àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà lórí dídábòbo olú ibùdó gbọ̀ngàn wọn (FHQ).

O ṣe igboriyin yii lasiko to ṣe abẹwo si gbọngan awọn ọmọ ogun Naijiria (NIGCON 1) lati lo ọjọ kan pẹlu awọn oludaabobo naa.


Lasiko abẹwo naa, Adari Ikọ naa, Ajagun James Nkereuwem ba Adari igbimọ sọrọ wéré lori awọn eto ati aṣeyege Ẹka naa lati igba ti wọn ti gunlẹ si agbegbe iṣẹ wọn.
Ajagun Sawyer wa ṣe sagankata fun adari aṣoju naa fun iṣakoso to lòye ati ifọkansi ti wọn n ṣe ti wọn si ti fi opin si ọran ole jija ni gbọngan ibudo FHQ. O yin awọn ọmọ ologun fun iwa ikoraẹni nijanu ati bi wọn ṣe ṣafihan ọmọ ẹgbẹ ologun fun ṣiṣe iranlọwọ iṣẹ ipese alaafia.
Leave a Reply