Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu yóò ṣe ìjíròrò lórí àjọṣepọ̀ ìpínsíméjì pẹ̀lú UAE

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 249

Ààrẹ Naijiria, Bọla Ahmed Tinubu, yóò lọ sí Abu Dhabi lẹ́yìn tí ó bá kúrò ní New Delhi, India láti ṣe ìjíròrò lórí àjọṣepọ̀ apá méjì láàrin Nàìjíríà àti United Arab Emirates.

Alaye kan ti oludamọran pataki fun aarẹ lori ibaraenisọrọ ati ipolongo,Oloye Ajuri Ngelale, buwọlu tun sọ pe aarẹ  yoo tun ṣe ijiroro lori fifagile iwe irinna ti UAE ṣe lori awọn ọmọ Naijiria.

Image

 

Ngelale sọ pe aarẹ Naijiria fẹ lo anfaani isinmi diẹ lori irin ajo naa lati tẹsiwaju lori igbelarugẹ erongba ọrọ aje rẹ  pẹlu awọn awọn to niiṣe ni ikọ ijọba ati aladaani United Arab Emirates.

Image

O tun wa fikun ninu alaye naa pe aarẹ ni lọkan lati yanju  ifidimulẹ adehun ifunni ni iwe irinnna to wa laarin Naijiria ati UAE.

Minisita fun idagbasike eto ọkọ ofurufu, Festus Keyamo yoo darapọ mọ aarẹ ti wọn yoo si jọ pada si Abuja lẹsẹkẹsẹ lẹyin ijumọsọrọ apa meji naa

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button