Nínú àtẹ̀jáde orin ti wọ́n gbé jáde lórí console fún ti NBA 2K24, ìràwọ akọrin Afrobeats, Burna Boy wà lára àwọn akọrin ti orin rẹ̀ yóò lù jade nínú ẹsẹ orin ọdún yi.
Lẹ́yìn èyí tó gbé jáde ní ọdún 2018 to pè ni ‘‘YE,’ Burna Boy ti di gbajúgbajà akọrin tó làlùyọ ni ilẹ̀ Áfíríkà.
Ní Ọdún 2022, àgbáyé fi ọwọ́ sí orin rẹ̀ tó pe àkọ́lé rẹ̀ ni ‘Last Last’, o sì ṣeéṣe kó jẹ òhun ni ó fẹ́ lò fún ti NBA 2K24..
Burna Boy gbé orin ẹlẹ́ẹ̀keje rẹ̀ jáde tó pè ní ‘I Told Them’, eléyìí tó gba ipò kinní lórí àtẹ UK Official Albums ti akọrin ilẹ̀ Adúláwọ̀ yóò kọ.
Yóò dara pọ̀ mọ́ àwọn ìràwọ̀ ní àgbáyé bii Lil Wayne, Central Cee, Steve Lacy,
fún ti ẹsẹ orin ti NBA 2K24 aládùn ti ọdún 2023.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply