Take a fresh look at your lifestyle.

Àjọ OYSIEC Ti N Gbaradi Fún Ètò Ìdìbò Ìjọba Ìbílẹ̀: Ààrẹ Isiaka Olagunju

0 315

Alága Àjọ Elétò Ìdìbò Ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, (Oyo State Independent Electoral Commission, OYSIEC), Ààrẹ Isiaka Olagunju ti ké sí àwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ láti tu yááyá ní ọjọ́ ìdìbò ìjọba Ìbílẹ̀ ti yóò wáyé ni Oṣù Kẹrin Ọdún to n bọ, láti dìbò fún ẹni yòówù tó bá wù wọn ni ọjọ́ ìdìbò.

Alága OYSIEC lo sọ ọ̀rọ̀ yìí níbi ètò ìfọ̀rọ̀wérọ̀ eléyìí tí Ẹgbẹ Akọroyin ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ (Oyo NUJ Correspondents’ Chapel) ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ ni ilé ẹgbẹ́ wọn tó wà ní agbègbè Mokola ni ìlú Ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà.

Nínú àlàyé rẹ̀, Ologunju jẹ kó di mímọ̀ pé, iṣẹ́ ìríjú Àjọ OYSIEC ni láti mójútó àti láti ṣe kòkáárí ètò ìdìbò, o wa fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, Àjọ náà ti n gbáradì láti rí dájú pé ètò ìdìbò yan Alága ati àwọn aṣojú Ìjọba Ìbílẹ̀ míràn lọ ní ìrọwọ́-rọsẹ̀

Nigbà tí Àjọ OYSIEC kò lágbára láti ṣètò ìforúkọsílẹ̀ olùdìbò gẹ́gẹ́ bí àlàyé rẹ̀, Olagunju jẹ́ kó di mímọ̀ pé àwọn yóò ṣe àmúlò àwọn ibùdó ìdìbò ti Àjọ INEC pèsè fún ètò ìdìbò gbogboògbò tó kọjá.

O wá tẹnu mọ pé, kò dín ní Ẹgbẹ̀rún Mẹ́fà ibùdó ìdìbò (6000 polling units) to wà jákèjádò Ìjọba Ìbílẹ̀ Mẹtalelọgbọn (33 LGA’s) ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, nínú èyí ti oṣiṣẹ elétò ìdìbò mẹta yóò má mójútó ibùdó ìdìbò kọọkan, eléyìí tó fihàn pé, Àjọ OYSIEC yóò nilo àwọn òṣìṣẹ́ yi kò dín ní Ẹgbẹ̀rún Méjìdínlógún (18,000).

Bákan náà ni Alaga OYSIEC tun ṣàlàyé pé, àjọ náà yóò bèèrè fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn ẹṣọ elétò áàbò láti rí dájú pé ohun gbogbo lọ déédéé.

Ṣáájú nínú ọ̀rọ̀ ìkíni káàbọ̀ rẹ̀, ẹni tíì ṣe Alága Ẹgbẹ́ Akọroyin, Raji Adebayo lù Àjọ OYSIEC lọgọ ẹnu, tó sì fi àsìkò náà gbà Alága rẹ̀ níyànjú láti ṣe ohun gbogbo tó wa ni ìkáwọ́ rẹ̀ láti rí pé ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ ṣe àṣeyọrí.

Lára àwọn tó kọ́wọ̀ọ́ rìn pẹlu Alága OYSIEC ní àwọn Kọmísánnà Àjọ náà bíi Babatunde Adeniyi, Olóyè Kunmi Agboola àti Emmanuel Olarewaju.

Abiola Olowe.
Ìbàdàn

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button