Take a fresh look at your lifestyle.

Ìrìn Àjò Hajj Ọdún 2024: Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Rí Ààyè (1,386)

0 249

Ni igbaradi fún Hajj ọdún 2024, Àjọ to n ṣe kokaari ìrìn àjò Hajj ni Orilẹ èdè Nàìjíríà (NAHCON) ti pèsè ààyè ti kò dín ní (1,386) sílẹ̀ fún Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Ẹni tíì ṣe Alága ìgbìmọ̀ ìrìn àjò sí ilẹ̀ mímọ́ (ẹ̀ka ti Mùsùlùmí) ni Ìpínlè Ọ̀yọ́, Sheik Hashim Abdul-wahab Olamide Atere lo sísọ lójú ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn ìpàdé pẹ̀lú Alága NAHCON, Alhaji Kunle Hassan ni ìlú Abuja tii ṣe olú ìlú Orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde tí Komisanna fún Ìròyìn àti Ìlanilọ́yẹ ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Dọtun Oyelade ṣe fi ìdí rẹ múlẹ̀ pé, Atere, ẹni tó ti lọ ṣe ìpàdé ní ìlú Abuja láti ṣe àgbéyẹ̀wò ìrìn àjò Hajj ọdún 2023, lo ṣàlàyé pé, Àjọ NAHCON ti bẹ̀rẹ̀ sí gbáradì fún Hajj ọdún 2024, nígbà tó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, ètò yóò bẹ̀rẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fún gbogbo àwọn tó bá n lọ.

Nígbà tó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn Akẹkọọgboye ẹlẹṣin Islam ni ìlú Sáúdí ti ṣèlérí láti rí dájú pé Àjọ náà yóò ṣe àṣeyọrí. Sheikh Hashim wa fi kún pé lára àwọn tó fẹ́ láti rin ìrìn àjò mímọ́ ti ọdún tó n bọ náà ló ti n dá owó irin àjò wọn.

O wá rọ gbogbo àwọn tí kò ti máa dá owó, ti wọn sì n fẹ lọ sí Hajj ọdún tó n bọ lati bẹ̀rẹ̀ síi ṣe bẹ́ẹ̀ sí inú àpò asuwon Àjọ náà ṣáájú àsìkò ti NACHON yóò kéde iye owó ìrìn àjò.

Àjọ NAHCON náà ló ti sọ tẹlẹ pé o ṣeéṣe kí òwò irin àjò ọdún to n bọ gbẹnu sókè látàrí owó Dollar to lọ sókè, o wá gba àwọn tó fẹ rin irin àjò náà níyànjú láti ni owó tó tó Mílíọ̀nù Mẹrin ààbò náírà (N4.5m) ni ìpamọ́ ko tó di ìgbà tí igbimọ Hajj yóò kéde owó ìrìn àjò ọdún.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button