Take a fresh look at your lifestyle.

Gómìnà Ọyọ buwọ́lu yíyan ọba Ṣoun ti ìlú Ogbomọsọ tuntun

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 204

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọyọ, Seyi Makinde, ti buwọ́lu yíyan ọmọ ọba Afọlabi Ghandi Ọlaoye gẹ́gẹ́ bí Ṣoun ti ìlú Ogbomọsọ tuntun.

Kọmiṣọna fun ijọba ibilẹ ati ọrọ Oye, Olusegun Olayiwola, sọ eyi ninu ọrọ rẹ kan pe, kikede yii wa lẹyin eto ọlọjọ gbọọrọ to wa labẹ ofin to wa nilẹ.

Olayiwola  wa sọ pe; “ Gomina wa ki ṣọun tuntun ku oriire bi o ṣe gori Itẹ Babanla rẹ.”

O sọ pe ọba tuntun ti wọn yan ni lati mu irẹpọ, igbọraẹniye ati ifaramọ laarin awọn eniyan.

Kọmiṣọna tun wa rọ awọn ọmọ ilu Ogbomoso lati fọwọsowọpọ pẹlu ọba naa fun ilọsiwaju aṣeyege awọn Babanla rẹ.

Ẹni to kuro lori oye, Ọba alayeluwa, Ọba Jimoh Oladunni Oyewumi, Ajagungbade Kẹta, jẹpe ọlọrun ni ọjọ kejila, oṣu kẹjila, 2021, ni ọmọ ọdun mọkanlale- lọgọgun.

Oba Oyewunmi gun ori oye ni ọjọ kẹrinle-logun, oṣu kẹwa, 1973 ti o si wa lori Itẹ naa fun ọdun mẹjidin-laadọta.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button