Ó lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún àwọn tó kú diẹ fún láti ìjọba ìbílẹ̀ Zamfara tí wọ́n ti jẹ ànfààní itọju ọ̀fẹ́ iṣé abẹ àti ògùn láti ilẹ ìwòsàn ìjọba
Bí ìròyìn ti fi tó wa létí Sẹ́nítọ̀ Sahabi Ya’u, to wa láti ẹgbẹ́ òṣèlú APC ni ó’ ṣẹ agbáterù ètò náà, ètò yìí wáyé ni ọjọ́ ẹtì ni ilé ìwòsàn ìjọba Kaura-Namods ni ìjọba ìbílẹ̀ Kaura Namoda ni ìpínlẹ̀ Zamfara.
Aṣojú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin náà tó wà pẹ̀lú àwọn alákoso ètò náà Alhaji Abba Isah, sọ wí pé ètò Ìrànlọ́wọ́ yii wà fún àwọn tó kú diẹ fún àti àwọn tí kò sí àgbàrá fún lati ṣe ìtọ̀jú ará wọn
Adarí ilé ìwòsàn náà , Oníṣègùn Kamal Umar sọ wí pé ó tí to àwọn márùn-ún lẹ lógbón akosemose, Dọ́kítà, nọ́ọ̀si, àti àwọn Òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn tó ti kópa nínú ètò náà
Umar ni ibi gbogbo ni àwọn yóò ṣíṣe dé nipa àwọn àìsàn ki àwọn tó wà ba le lẹ lọ sí ilè wọn pẹ̀lú àlàáfíà.
Ó ní àwọn àìsàn bi ,ifunpa, àìsàn Suger, iṣé abẹ àti bẹẹ bẹẹ lọ. Ni àwọn yóò ṣiṣẹ́ lé lórí.
Leave a Reply