Mínísítà fún eto ọrọ èpò rọbi lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Sẹnetọ Heineken Lokpobiri, tí tún ṣé ìpinnu ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà látí fòpin sí bí wọ́n ṣé ń jí èpò rọ̀bì ní Niger Delta ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ó sọ pé àwọn ìwà wọnyí ló ń fá ètò ọ̀rọ̀ ajé orílẹ̀-èdè yìí sẹyìn.

Mínísítà náà sọ èyí lásìkò àbẹwò rẹ̀ sí Niger Delta, Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bí ará ikọ kàn tó ń ṣé àbẹwò sí àgbègbè náà lórí bí wọ́n tí lé gbèjà kó ole èpò rọbi tó n lọ lọ́wọ́ ní ẹkùn èpò rọbi ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ẹ rántí pé Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Bola Ahmed Tinubu tí rán ikọ̀ kàn lọ sí àwọn ìpínlẹ̀ Niger Delta fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò lójú-ẹsẹ̀ lórí báwọn èèyàn ṣe ń gbógun tí ole èpò rọbi ní Niger Delta ti Mínísítà fún ètò ààbò, Muhammed Badaru àti Mínísítà tí Ìpínlẹ̀ fún ọ̀rọ̀ Èpò Rọ̀bì (Èpò), Heineken Lokpobiri, Mínísítà fún Ìpínlẹ̀ fún Ọrọ Èpò Rọ̀bì (Gáàsì), Ekperipe Ekpo, Àkọwé àgbà tí Ilé-iṣẹ́ Ọrọ Èpò, Ambassador Gabriel Aduda, Olùdámọ̀ràn Ààbò Orílẹ̀-èdè yìí, Mallam Nuhu Ribadu, àti àwọn alabaṣepọ pàtàkì mìíràn.
Leave a Reply