Ilé alájà méjì tí dàwó lulẹ̀ ní agbègbè Garki, Abùjá ní alẹ́ ọjọ́ Ọjọ́rú.
Ní ìgbà to n fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ fún àwọn oníròyìn, ọ̀gá àgbà àjọ tó ń rí ṣí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì, Dokita, Abbass Iddriss sọ pé ènìyàn mẹ́tàdínlógójì ni wọ́n ti dóòlà ẹ̀mi wọn, Méjì nínú wọn ló sì farapa yánayàna, wọ́n sì ti gbé wọn lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú ní Abùjá.
![]()
Ọ̀gá àgbà àjọ náà tún sọ síwájú sí pé, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì tún kú ti wọ́n ń wá tí wọ́n kò tí rí. Ó wá dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn àti lájọlájọ tó jọ̀wọ́ ara wọn sílẹ̀ láti dóòlà ẹ̀mí àwọn èniyàn nígbà tí wọ́n ń dúró de ohun èèlò láti tẹ̀síwájú nínú wíwá àwọn èniyàn tó nù kiri.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply