Take a fresh look at your lifestyle.

Mínísítà fún eré ìdárayá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, pè fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn tó nííṣe

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 251

Minisita tuntun fun idagbsoke ere idaraya, Sẹnetọ John Owan Enoh ti pe fun ifọwọsowọpọ ati ijumọṣepọ pẹlu àwọn tó nííṣe ninu ati lode awọn ile iṣe idaraya lati mu idagbasoke ba ikọ naa gẹgẹ bi awọn ẹlẹgbẹ rẹ.

Minisita pe ipe yii ni ile iṣẹ rẹ ni papa iṣere Moshood Abiola, Abuja, laipẹ lẹyin ti o bẹrẹ iṣẹ.

O sọ pe aarẹ Asiwaju Bọla Ahmed Tinubu nifẹsi idagbasoke ere idaraya lorilẹ-ede ati pe idi niyi ti o fi yan Minisita lati dari idagbasoke ikọ naa pẹlu ọgbọn rẹ.

Sẹnetọ Enoh ṣalaye pe ijumọṣiṣẹpọ ṣe pataki, paapaa julọ nitori pe ere idaraya kii ṣe nnkan to mu iṣọkan ba awọn ọmọ Naijiria nikan sugbọn ti o tun jẹ ikọ pataki to n ko to lami ninu idagbasoke ajọṣepọ ọrọ aje orilẹ-ede.

Minisita wa pinnu ifọkansi rẹ lati ṣe aṣeyege ni ikọ naa pẹlu ilana  iṣakoso yii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button