Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọyọ ti buwọ́lu ìyọ̀ǹda owó yíyá láti fi ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ fún àwọn olùkọ́ni ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ jákèjádò gbogbo ikọ̀ ní ìpínlẹ̀.
Alakooso oludari igbimọ eto ẹkọ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti ipinlẹ Ọyọ (OYOSUBEB), Jacob Dairo sọ pe owo naa jẹ inalọọrun fun awọn olukọni.
Dairo sọ pe owo naa ti wọn yoo pin ni isọri, jẹ lati pese irọrun si ipa imukuro owo adinku epo ilẹ lori awọn olukọni ipinlẹ Ọyọ”
O sọ pe eto naa waye pẹlu afọwọsi gomina ipinlẹ, Seyi Makinde, ti o paṣẹ pe ki wọn fun awọn olukọni ni owo yiya naa lai figba kan bọkan ninu.
Dairo wa gba awọn to janfaani owo yiya yii, ti awọn ile ifowopamọ ṣagbekalẹ fun wọn, ti wọn yoo si san pada laarin ogoji oṣu fun idi ti wọn fi gba owo naa.
Ni bayii, Kọmiṣọna fun eto ẹkọ, imọ ijinlẹ ati imọ ẹrọ, Ọjọgbọn Salihu Abdulwaheed wa sọ pe oun ti gbaradi lati ṣiṣẹ pẹlu awọn to niiṣe ninu ẹka eto ẹkọ.
Leave a Reply