Take a fresh look at your lifestyle.

Ọ̀fẹ́ Ni Béèlì Fún Afurasí Oníjìbìtì Tàbí Ọ̀daràn – Àjọ EFCC

0 246

Àjọ to n gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ àti ṣíṣe owó kúmọkùmọ, EFCC ti jẹ́ kó di mímọ̀ pé ọ̀fẹ́ ni béèlì (Administrative Bail) fún afurasí tó bá wà ní àhámọ́ àjọ náà.

Ẹni tíì ṣe Adelé Ọ̀gá Ẹkùn Ìbàdàn àjọ EFCC, ACE I Halima Mustapha Rufa’u lo sísọ lójú ọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó n gba àlejò àwọn igbimọ Àgbáríjọ Ẹgbẹ́ Agbẹjọro (NBA), ẹ̀ka ti ìlú Ìbàdàn, ti Alága rẹ̀, Folashade Aladeniyi le iwájú rẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde tí Wilson Uwujaren tíì ṣe Olori ẹ̀ka Ìròyìn àti Ìkéde fún Àjọ náà fi s’ọwọ sí àwọn oníròyìn ní ìlú Ìbàdàn tíì ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni Ẹkùn Gúsù Ìwọ̀ Oòrùn Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà ṣe fí ìdí rẹ̀ múlẹ, pé àjọ EFCC kó bèèrè fún owó ìdúró (Bail) lọ́wọ́ agbẹjọ́rò tàbí ìdílé afurasí kankan kí wọ́n tó gbà òmìnira kúrò ninú àhámọ́.

Adelé Ọ̀gá Ẹkùn náà wà fi àsìkò ìgbàlejò náà kìlọ̀ fún àwọn agbẹjọ́rò láti dẹ́kun ṣíṣe oníìdúró fún afurasí, nígbà tó tẹnu mọ pé irufẹ ìgbésẹ̀ bẹẹ máa n ṣokùn fa wàhálà fún agbẹjọ́rò, tó sì tún tàbùkù iṣẹ́ wọn.

Rufa’u wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà tó kìlọ̀ pé ni ìgbàkigbà ti afurasí ba ṣe lòdì sí àlàkalẹ̀ àjọ EFCC, àjọ náà yóò kọ́kọ́ fi ọwọ́ sìnkún òfin mu irú agbẹjọ́rò náà kó tó mú gbogbo àwọn tí ṣe oníìdúró yòókù.

Nígbà tó n fèsì, Alága ìgbìmò náà, Folashade Aladeniyi fi àsìkò náà lu Ẹkùn Ìbàdàn àjọ EFCC lọgọ ẹnu fún iṣẹ takuntakun tó n ṣe lati dẹkun onírúurú ìwà jibiti àti àwọn ìwà ìbàjẹ́ míràn ni Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Bákan náà ni Aladeniyi fi àsìkò náà rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Adari Ẹkùn àjọ EFCC, láti ṣe àmójútó ẹtọ àwọn afurasí tó wà ní àhámọ́ nípa rírí dájú wí pé wọn gbà òmìnira ni kánkán, nígbà tó tún gbà wọn níyànjú láti ṣe ìwádìí lórí ìhùwàsí àti ìṣe àwọn olóṣèlú.

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button