Lára ọ̀nà láti dènà àjàkálẹ̀ àrùn láti ara ẹran jíjẹ, Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ile iṣẹ ìjọba Àpapọ̀ tó n ṣàkóso Iṣẹ́ Àgbẹ̀ àti Ìdàgbàsókè Ìgbèríko (Federal Ministry of Agriculture and Rural Development) pèsè Ọkọ̀ Amóhuntutù (Refrigerated Meat Van) fún àwọn Alápatà ni ọjà Amosun.
Àtẹ̀jáde ti Kọmísánnà fún Ìròyìn Dọtun Oyelade fi síta lo jẹ kó di mímọ̀ pé, Kọmísánnà fún Iṣẹ Àgbẹ̀ àti Ìdàgbàsókè Ìgbèríko, Olasunkanmi Olaleye lo sàlàyé wí pé, ó léwu ki àwọn Alápatà máa fi ọkọ̀ tí kò nílé lórí kó ẹran, nítorí èyí lè fa àjàkálẹ̀ àrùn.

Olaleye wá tẹnu mọ pé, Ọkọ̀ Amóhuntutù yìí yóò dènà àjàkálẹ̀ àrùn, ti yóò sì dáàbò bo àwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti ohun ìní wọn. Nígbà tó fi kún àlàyé rẹ̀ pé láìpẹ́, ìjọba yóò béèrè fún ìbáṣepọ̀ àwọn Alápatà àti olùdóòkòwò láti pèsè Ọkọ̀ Amóhuntutù míràn, eléyìí tí yóò mú kí wọn máa pèsè ẹran fún títà lọ́nà ìmọ̀tótó fún àwọn ará ìlú.
Olaleye wá gba àwọn ẹgbẹ́ Alápatà náà níyànjú láti lo Ọkọ̀ náà fún ohun tí wọn pèsè rẹ̀ fún, ki wọn sì gbárùkù ti àlàkalẹ̀ ìjọba Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.

Nígbà tó n fèèsì lórúkọ Alága Alápatà ni Orilẹ èdè Nàìjíríà, ẹ̀ka ti Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, ẹni tí ṣe Akọwe ẹgbẹ́, Olagoke Lateef lu Ìjọba Ìpínlẹ̀ ati Ìjọba Àpapọ̀ lọgọ ẹnu fún irú ìgbésẹ̀ yìí.
Olagoke wá ṣèlérí wí pé ẹgbẹ́ Alápatà yóò lo Ọkọ̀ náà ni ọ̀nà tó tọ́, to sì tun fi kún pé àwọn yóò fi ọwọ́ ṣọwọ́pọ̀ pẹ̀lú àlàkalẹ̀ ìjọba láti dènà àjàkálẹ̀ àrùn tó lè ti ara ẹran ti àwọn èèyàn bá jẹ.
Bakan náà ló fi àsìkò náà rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ìjọba láti kún ẹgbẹ Alápatà lọwọ nípa ìpèsè ètò ẹ̀yáwó ti yóò mú kí òwò wọn gbèrú síi.
Abiola Olowe
Ìbàdàn
Leave a Reply