Take a fresh look at your lifestyle.

Gómìnà Makinde Ní Ìbáṣepọ̀ Pẹ̀lú Ilé Iṣé IITA Látí Ri Wí Pé Ààbò Tó Dájú Wà Lórí Oúnjẹ.

0 212

Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo Seyi Makinde sọ wí pé ìjọba òun bá ilé iṣé International Institute Of Tropical Agriculture (IITA) do wọ pọ, láti rí wí pé ààbò tó péye wà fún oúnjẹ.

Nínú ọ̀rọ̀ àtẹ̀jáde kan láti ọwọ́ Akọ̀wé fún Gómìnà, ọ̀gbẹ́ni Sulaimon Olanrewaju, lọ sọ èyí  dì mímọ̀ ni ọjọ́ ìṣẹgun nígbà tí o gba àlejò Adarí àgbà fún ilẹ iṣé náà ọ̀mọ̀wé Simone Ehui.

Gómìnà Makinde tó gbàlejò Ehui àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ ní ilé igbalejo ìjọba ti o wà ní Ibadan, o dupẹ lọwọ ilé iṣé IITA fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wọn àti àtìlẹ́yìn wọn láti ìgbà tí o tí wọlé gẹgẹ bí Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́.

Ó ní ìgbésẹ náà jẹ́ èyí tí yóò ní àṣeyọrí nínú èyí tí yóò sì  mu inu ohun dun gidigidi.

Nínú ọ̀rọ̀ idupẹ rẹ Adarí ilé iṣé IITA ,to tun jẹ Adarí CGIAR ni agbègbè Áfríkà, o ní àwọn ẹgbẹ́ òun tí ṣetán láti ṣiṣẹ́ fún ààbò lórí oúnjẹ pẹ̀lú ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo

Ó wà fí dá Gómìnà lójú wí pé àwọn yóò ṣe àtìlẹ́yìn fún wọn ní gbogbo ọ̀nà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button