Ìyàwó ààrẹ orílẹ̀-èdè yìí tẹ́lẹ̀ rí, Dame Patience Jonathan ti ṣèlérí láti ṣe
àtìlẹ́yìn fún Iyawo ààrẹ, sẹ́netọ̀ Oluremi Tinubu Oluremi Tinubu.

Ìyáàfin Jonathan se ìlérí yí nígbà tí ó se àbẹwò ọlọ́lá sí Ìyàwó ààrẹ, obìnrin àkọ́kọ́, Oluremi Tinubu ní ìlú Àbújá. Ó se àpèjúwe àbẹ̀wò náà gẹ́gẹ́ bi àbẹwò atìlẹ́yìn fún ìyàwó ààrẹ.

Ó sọ fun àwọn obìnrin orílẹ̀-èdè yìí pé, ìyáàfin Tinubu yóò kó wọn dé èbúté ògo pẹ̀lú ètò rẹ̀ “Renewed Hope for all.”
Iyaafin Tinubu sọ ìdí tó fi yẹ kí wọ́n tú àwọn ọ̀dọ́ kọ́ kí wọ́n sì tún fún wọn ní ọjọ́ ọ̀la tó dára ni igba ti awọn agba oloye ninu ẹgbẹ́ National Council for Women Societies, NCWS se àbẹwò Olola sí ní Àbújá.

Ààrẹ ẹgbẹ́, Hajiya Lami Lau ló ṣáájú ikọ̀ náà, wọ́n sì ṣe ìlérí atìlẹ́yìn fún ètò arábìnrin àkọ́kọ́-Renewed Hope Initiative project. Eto náà wà láti bù òróró ìtura sínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbí. Wọ́n gbájúmọ́ ètò ọ̀gbìn, ìlera, ẹkọ, ìdókòwò àti ìrónilágbára ọrọ̀ ajé.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply