Orílẹ̀-èdè Niger: ECOWAS Yóò Ṣé Ìjíròrò, Ló Ọ̀gbọ́n Àtínudá Látí Dá Ìjọba Tiwa-n-tiwa Pàdà Sí Àkóso Niger
Ọlálékan Ọ̀rẹ́núgà
Alága tí ECOWAS àti Ààrẹ Nàìjíríà Bola Tinubu, sọ pé ẹgbẹ́ náà yóò tẹ̀síwájú látí ló ọ̀gbọ́n ètò òṣèlú Tiwa-n-tiwa àtí ṣé Ìjíròrò pẹ̀lú gbogbo àwọn alẹnu-lọrọ, látí mú ìjọba tiwantiwa pàdà sípò ní Orílẹ̀-èdè Niger.
Alága àtí Aláṣẹ ECOWAS sọ ní Ọjọ́bọ̀ ní ìlú Abuja níbí ìkíni káàbọ̀ àpéjọ ẹlẹẹkeji lórí ipò àwùjọ ọrọ̀ òṣèlú ní Orílẹ̀-èdè Niger.

Nígbà tó ń ṣé àfihàn pàtàkì ìpàdé náà, Ààrẹ Tinubu tẹnumọ pé ìtẹ̀síwájú lórí ọrọ náà ṣé kókó, bẹ́ẹ̀ ló ṣé àfihàn àwọn ìgbìyànjú ẹgbẹ́ náà àti àwọn aṣojú pàtàkì láti ṣé ìjíròrò pẹ̀lú àwọn àlẹ́nú-lọ́rọ́ láàrín ẹgbẹ́ náà atí kàákiri ilẹ̀ Adúláwọ̀.

Níbí ìṣídé ayẹyẹ náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn Ààrẹ tí Guinea Bissau, Senegal, Cote’d ‘Ivoire, Ghana, Benin, Sierra Leone, àtí Togo, nígbàtí Liberia àtí Gambia rán àwọn Mínísítà ilẹ̀ òkèèrè wọ́n gẹ́gẹ́ bí aṣojú.

Àwọn Ààrẹ Orílẹ̀-èdè tí kìí ṣé Ọmọ ẹgbẹ́ ECOWAS tó wà ní ìpàdé náà ní Ààrẹ Mauritania àti Burundi.
Leave a Reply