Ààrẹ Tinubu Yóò Bá Àwọn Ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Sọ̀rọ̀ Lórí Ẹrọ Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Orílẹ̀-èdè Yìí
Ọlálékan Ọ̀rẹ́núgà
Ààrẹ Bola Tinubu yóò ṣé àwọn ìkéde kàn sí àwọn orílẹ̀-èdè yìí ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kọkanlelọgbọn 31, Oṣù Keje ọdún 2023 ní àgó mẹ́fà ìrọlẹ́ (18:00 GMT).
Agbẹnusọ fún Ààrẹ, Dele Alake, ló fí èyí hàn nínú àtẹ̀jiṣẹ́ kàn tó fí síta ní òwúrọ̀ ọjọ́ Ajé.
Ó rọ àwọn ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n àti rédíò àti àwọn ilé iṣẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ látí dárapọ̀ mọ́ ìkànnì National Television Authority NTA àti Radio Nigeria fún ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ náà.
Ó n’ìrètí pé Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ náà yóò dá lórí àwọn italaya tí Orílẹ̀-èdè náà ń kojú lọ́wọ́lọ́wọ́ pàápàá ìnira tó wá lẹyìn ìyọkúrò owó ìrànwọ́ orí èpò bẹntiroolu (PMS).
Leave a Reply