Aláṣẹ tí àwọn olórí orílẹ̀-èdè àti ìjọba tí ẹgbẹ́ Ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà (ECOWAS) tí rán Ààrẹ Orílẹ̀-èdè Benin, Patrice Talon lọ́ sí Niamey, Republic of Niger, látí lọ́ dẹkùn ìdààmú òṣèlú ní orílẹ̀-èdè náà.
Alága tí ECOWAS àti Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Tinubu, sọ èyí fún àwọn oníròyìn Ilé-iṣẹ́ Ìjọba àpapọ̀, lẹyìn tí òún Ààrẹ Talon ṣé ìpàdé lẹyìn ilẹkùn ní Abuja.
Ó ní: “Ó ń lọ síbẹ̀ nísinsìnyí; o tí wà ní ọnà rẹ̀ bayii sí Niger Republic.”
Ìpàdé láàrín àwọn Olùdarí méjèèjì jẹ́ tí pajawiri látí lè wá ọnà àbáyọ́ sí rògbòdìyàn tó ń lọ́ lọ́wọ́ ní Niger Republic.
Bákan náà, Ààrẹ orílẹ̀-èdè Benin, Patrice Talon tó ń ṣèbẹ̀wò sí orílẹ̀-èdè Niger Republic tó wà ní àdúgbò rẹ̀ jẹ́ oun tó le gan-an, ó sì yẹ kí wọ́n gbé ìgbésẹ̀ kíákíá láti ṣé àtúnṣe sí.
Talon sọ ìrètí rẹ̀ pé òún gbàgbọ́ pé ìgbésẹ ECOWAS náà yóò yọrí sí réré.
Leave a Reply