Take a fresh look at your lifestyle.

Àjọ UBEC Gbóríyìn Fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara Fún Àtìlẹ́yìn Rẹ Lórí Àwọn Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba.

0 169

Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara ni  àjọ UBEC ti Gbóríyìn fún látàrí iṣẹ takuntakun rẹ nípa awọn ilé ẹ̀kó ìjọba 

Wọn gbé ọ̀sùbà o káre fún pẹ̀lú ipá ti o ń kọ pẹ̀lú ilé iṣé ẹ̀kọ́ ti ìjọba láàrin àsìkò pè rète ti won dá ilé ẹ̀kó ìjọba náà sílẹ̀.

Akọ̀wé àgbà fún ìjọba lórí  ẹ̀tọ́ ẹ̀kọ́ (UBEC) ọ̀mọ̀wé Hamid Boboyyi to ṣe àbẹ̀wò sí àwọn ilé ẹ̀kó tuntun náà ni, nínú òun dùn gidigidi sí ohun tí òun rí àti bí ẹ̀rọ àwọn ìgbàlódé ṣe wa níbè fún ẹ̀kọ́ to yẹ kóró fún àwọn akékòó.

Àjọ UBEC ni  o ń ṣe  ìbẹ̀wọ̀ ọlọ́jọ́ méjì sí ìpínlẹ̀ náà.

Ọjọ́ ẹtì ni wọn dé sí ìpínlẹ̀ Kwara, wọn sì ṣe àbẹ̀wò sí ilé ìwé Model smart ni Adeta ati àwọn ilé ìwé ìjọba míràn.

Bákan náà won ṣe ìbẹ̀wọ̀ sí igbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara, Kayode Alabi,to si kí wọn káàbò lórúko Gómìnà.

Boboyyi Gbóríyìn fún ìjọba àpapọ̀ pẹ̀lú àtìlẹ́yìn ti o n ṣe lọ́wọ́ nípa ètò ẹ̀kọ́.

Igbákejì Gómìnà ni ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara ni ìjọba àwọn yóò túnbọ̀ tèsíwájú nípa sí ṣẹ àtìlẹ́yìn fún àjọ UBEC, èyí tí yóò mú ìdàgbàsókè bá ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́.

Ó wà rọ akọ̀we àgbà fún ìjọba nípa ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ̀ ẹ̀kọ́ láti wọ àwọn Ìpèníjà ti o n kojú àwọn ilé ìwé tó kùn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button