Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu Tí Ń Ṣètò Tó Dájú Lórí Ààbò Àti Òṣì – Ìgbákejì Ààrẹ Shettima

Ọlálékan Ọ̀rẹ́núgà

0 369

Ìgbákejì Ààrẹ Nàìjíríà, Kashim Shettima sọ ​​pé ìṣàkóso Ààrẹ Bola Tinubu láàrín àwọn ọsẹ díẹ̀ tó mbọ̀ yóò ṣé àfihàn ètò tó dájú lórí Ààbò àti òsì, láàrín àwọn italaya mìíràn tó ń kojú àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà pàápàá jùlọ ní àgbègbè àríwá.

Ìgbákejì Ààrẹ sọ́ eléyìí ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ kẹrindinlogun oṣù keje nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú àwọn òníròyìn nígbà tó n ṣé àbẹwò ìtùnú sí ìpínlè Kano, Nàìjíríà.



Gómìnà ìpínlẹ̀ Kano Abba Yusuf ló gbàléjò Igbákejì Ààrẹ tó ṣé àbẹ̀wò náà pèlú Ìgbákejì Ààrẹ Ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà Sen. Barau Jibrin pẹ̀lú àwọn mìíràn lọ́ sí ilé Emir Bichi, HRH, Alhaji Nasiru Ado Bayero, níbí tó tí bá wọ́n kẹdun nípa ikú Imam Galadanci, bó sé fí ọrọ Ààrẹ Tinubu jíṣẹ́.

Ìgbákejì Ààrẹ ṣé àfihàn ìbánikẹ́dùn Aare Bola Tinubu, o sí gbàdúrà sí Ọlọrun láti fún olóògbé náà ní ìsimi ayérayé. Bẹ́ẹ́ náà ló kí gbogbo àwọn ẹbí Galadanci.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button