Take a fresh look at your lifestyle.

Wizkid Ṣetán Láti Gbé Ọ̀tun Orin Jáde

0 305

 

Gbajúmọ̀ Olórin ni,Wizkid ti ṣetán láti gbé orin oní Fídíò kan jáde.

Ní ọjọ́ kejìlélógún oṣù. yìí, Wizkid fi léde lórí ẹ̀rọ ayélujára pé òun yóò gbé àwo tuntun oní Fídíò jáde ní ọṣẹ to ń bọ̀.

Ó sọ èyí ní ìgbà tí ó ń se àyẹ̀wò pápá isere Tottenham Hotspur ti ìgbàgbọ́ wà pé yóò ti se
eré ní ọjọ́ Àbámẹ̀ta, ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù keje, ọdún 2023.

Ó jẹ kó di mímọ̀ pé. ó ti di dandan kí òun gbé àwo àkọ́kọ́ ti ọdún yí jáde ní ọ̀ṣẹ̀ tó ń bọ̀ lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ wa lẹ̀nu wò.

Àwọn Olólùfẹ́ rẹ̀ yóò máà retí àwo orin karùn ún rẹ̀ lẹyìn àkọ́lé bíi: ‘More Love’, ‘Less Ego’ , ‘Bad To Me’ ati‘ ‘Money & Love’.

Wizkid jẹ́ akorin Adúláwọ̀ àkókò ti yóò kọkọ lo pápá-ìseré Tottenham Hotspur tó lè gba ogorun egberun eniyan lẹẹkan lati sere, yóò sì tún
fi àwo rẹ̀ tuntun rẹ léde ní ibẹ̀ ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, ọdún 2023.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button