Olùkọrin Ọmọ Nàìjíríà to ti gba àmì ẹ̀yẹ ‘Grammy’ , Damini Ogulu tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Burna Boy ti fi ìtàn balẹ̀ gẹgẹ bi ọmọ ilẹ̀ Adúláwọ̀ àkọ́kọ́ tí orin rẹ̀ máa jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà láti ọwọ́ ènìyàn Bílíọ̀nù kan káàkiri gbogbo àgbáyé. Wọ́n kéde èyí lórí ẹ̀rọ ayélujára Twitter ní ọjọ́ Ojóbọ̀.
Orin rẹ̀ ‘Last Last’ pẹ̀lú álúbọ̀mù mẹ́ta míràn àti àwọn kan ló gbèè lárugẹ tó fi ṣeéṣe.
Burna Boy tún jẹ́ Olukorin ilẹ̀ Adúláwọ̀ ti àwọn ènìyàn ń tẹ̀lé jù lórí àtẹ, pẹ̀lú ènìyàn tó ju Mílíọ̀nù mẹ́rin lọ.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply