Kọmisọna àgbà tí Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sí Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Richard Montgomery sọ pé àwọn ìpinnu ètò-ọrọ̀ àjé tí ìṣàkóso Ààrẹ Bola Tinubu ní a ṣé àkíyèsí kàákiri àgbáyé àti pé yóò fá àwọn oníṣòwò wàá sí orílẹ̀-èdè náà.
Montgomery sọ èyí ní Ọjọ́rú làkókò tó ń bá àwọn òníròyìn sọ̀rọ̀ lẹyìn ìpàdé rẹ̀ pẹ̀lú Ìgbákejì Ààrẹ Kashim Shettima ní ilé ìjọba Àpapọ̀, Abuja.

Ó ní yíyọ owó ìrànwọ́ èpò bẹntiroolu àti àtúnṣe òṣuwọn paṣipaarọ tí pèsè ààyè fún àwọn oníṣòwò ní Nàìjíríà.
Ó tún ṣé àfihàn igbamọra àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè yìí lásìkò tí Ààrẹ Tinubu yọ́ owó ìrànwọ́ èpò kúrò, Montgomery sọ pé Ìjíròrò òún pẹ̀lú ìgbákejì Ààrẹ dá lórí ìgbésẹ tí yóò ṣé ìrànwọ́ fún àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Leave a Reply