Take a fresh look at your lifestyle.

Akọ́ni-mọ̀ọ́gbá Waldrum Kọ Orúkọ Agbábọ́ọ̀lù Super Falcons Fún Ife Àgbáyé Ọdún 2023 Jáde

0 224

 

Akọ́ni-mọ̀ọ́gbá Randy Waldrum ti kọ Orúkọ àwọn mẹ́tàlélọ́gún ògbóntàrigì Obìnrin agbábọ́ọ̀lù Super Falcons fún Ife Agbaye Ọdún 2023 jáde. Ìdíje náà yóò wáyé ní Australia àti New Zealand, bẹ̀rẹ̀ láti ogúnjọ́ oṣù keje ọdún yìí.

Orúkọ wọn nìyí:

Asisat Oshoala, ti ikọ̀ ti Barcelona, Rashidat Ajibade ti Atlético Madrid, àti Onome Ebi.
Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wà ní ìsòrí ‘B’ pẹ̀lú orílẹ̀-èdè tó jọ gbàlejò rẹ̀ papọ̀, Australia, Canada, ati Republic of Ireland.
Naijiria yóò kọkọ wákò pẹ̀lú Orílẹ̀-èdè Canada ni ọjọ́ kọkànlélógún oṣù keje.

Àwọn agbábọ́ọ̀lù to ku ni wọ́nyi:
Àwọn Asọ́lé: Chiamaka Nnadozie (Paris FC, France); Tochukwu Oluehi (Hakkarigucu Spor FC, Turkey); Yewande Balogun (AS Saint-Etienne, France)

Àwọn adi ẹ̀yìn mí: Onome Ebi (Abia Angels); Osinachi Ohale (Deportivo Alaves, Spain); Glory Ogbonna (Besiktas JK, Turkey); Ashleigh Plumptre (Leicester City, England); Rofiat Imuran (Stade de Reims, France); Michelle Alozie (Houston Dash, USA); Oluwatosin Demehin (Stade de Reims, France)

Àárín gbùngbùn: Halimatu Ayinde (Rosengard FC, Sweden); Rasheedat Ajibade (Atletico Madrid, Spain); Toni Payne (Sevilla FC, Spain); Christy Ucheibe (SL Benfica, Portugal); Deborah Abiodun (Rivers Angels); Jennifer Echegini (Florida State University, US

Ọwọ́ Iwájú: Uchenna Kanu (Racing Louisville, Kentucky, USA); Gift Monday (UDG Tenerife, Spain); Ifeoma Onumonu (NY/NJ Gotham FC, USA); Asisat Oshoala (Barcelona Femenine, Spain); Desire Oparanozie (Wuhan Chegu Jianghan, China); Francisca Ordega (CSKA Moscow, Russia); Esther Okoronkwo (AS Saint-Etienne, France)

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button