Ààrẹ Bola Tinubu n se ìpàdé lọ́wọ́ lọ́wọ́ pẹ̀lú ajàjàn-gbara tẹ́lẹ̀ rí Niger Delta, Asari Dokubo ni gbọ̀ngán ààrẹ ní Àbújá.
Dokubo dé sí Aso Rock Villa ní déédé aago mọ́kànlá àárọ̀, ó sì bá ààrẹ se ìpàdé bònkẹ́lẹ́.
Ó kó àwọn ọ̀dọ́ Niger Delta jọ ní ọ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tó kọjá láti wà níbi ìgbẹ́jọ́ nípa ìbò ààrẹ tó wáyé ní Àbújá.
.
Ó jẹ́ alátìlẹ́yìn Tinubu tó gbupọn. Ó sì sọ ní ọjọ́ Ojobọ̀ fún àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè yìí pé tí orílẹ̀-èdè yìí bá kùnà, ààrẹ Tinubu ni kí wọ́n di ẹ̀bi rẹ̀ rù.
Nípa ti ìyọwọ́ kúrò lórí owó orí epo, ó sọ pé, àwọn ààrẹ àná Goodluck Jonathan àti Muhammadu Buhari ti yẹ kí wọ́n ṣe nǹkan tí Tinubu se láàrín ọ̀sẹ̀ mélòó kan.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply