Yíyá Akẹ́kọ̀ọ́ lówó : Nàìjíríà yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní fún wọn ní oṣù Ọwẹ̀wẹ́
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Ìjọba Nàìjíríà ti sọ pé òun ti ń ṣiṣẹ́ lórí ọ̀nà láti bẹ̀rẹ̀ fífún àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ ní owó yíyá nínú oṣù Ọwẹ̀wẹ́.
Akọ̀wé àgbà ti ilé iṣẹ́ ìjọba tó ń mójútó ètò ẹ̀kọ́, David Adejo sọ eléyìí nígbà tí ó ń dáhùn sí ìbéère àwọn akọ̀ròyìn ní Abuja, ní Ọjọ́ọ́rú.
A o ranti pe aarẹ Bọla Tinubu buwọlu ofin fifun awọn akekọọ lanfaani ati ya owó tíkò ní èlé lórí.
Gẹ́gẹ́ bí Adejo ṣe sọ, aarẹ Tinubu ti paṣẹ pe ki owo naa ti wa nilẹ fun awọn ti yoo kọkọ janfaani rẹ fun sáà ìkẹ́kọ̀ọ́ 2023/2024.
Leave a Reply