Gómìnà Nasarawa ṣèdárò àwọn tó farà gba ìjàm̀bá ọkọ̀ ojú omi ní Kwara
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Gómìnà ìpínlẹ̀ Nasarawa tí ó tún jẹ́ alága, ìgbìmọ̀ gómìnà Àríwá Àringbùngbùn, Abdullahi Sule, ti banújẹ́ lórí ikú àwọn àlejò onígbéyàwó tó lé lọ́gọ́ọ́rún, nínú ìjàm̀bá ọkọ̀ ojú omi tó wáyé ní ìjọba ìbílẹ̀ Patigi, Kwara .
Nínú àlàyé kan tí akọ̀wé àgbà fún ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀, Ibrahim Addra buwọ́lù, sọ pé àjálù náà mi Gómìnà Sule , tó tún wá jẹ́ àsìkò ayẹyẹ ìgbéyàwó.
“ Gomina lorukọ awọn gomina Ariwa Aringbungbun ati awọn eniyan agbegbe ṣedaro pẹlu gomina ati awọn eniyan ipinlẹ Kwara ati awọn ẹbi awọn to padanu emi wọn.
“ Adura wa ki o lọ ba awọn yooku wa, Gomina Abdulrahman Abdulrazaq, ati awọn eniyan ipinlẹ Kwara lasiko yii.”
Ó wá túnbọ̀ gbàdúrà kí ọlọ́run tẹ́ àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn sí afẹ́fẹ́ rere, kí ọlọ́run ó sì rọ́ àwọn ẹbí wọn lójú.
Leave a Reply