Ààrẹ Bọla Ahmed Tinubu, GCFR, ti buwọ́lu kí alága ìgbìmọ̀ tó ń mójútó ọ̀ràn ọrọ̀-ajé àti ìnáwó (EFCC), Ọ̀gbẹ́ni AbdulRasheed Bawa, fìdíẹ̀ mọ́lé fúngbà tí kò lọ́jọ́ ná, láti le ṣe ìwádìí bó ṣe ṣe iṣẹ́ rẹ̀ nígbà tó wà lọ́ọ́físì.
Gẹ́gẹ́ bí àlàyé kan tí adarí ètò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ní ọ́fíísì akọ̀wé fún ìjọba àpapọ̀, Willie Bassey ṣe, ó sọ pé eléyìí wáyé nítorí ẹ̀sùn ìwà ìbàjẹ́ tí wọ́n kà si lẹ́sẹ̀.
“Wọn ti paṣẹ fun Ọgbẹni Bawa ko fa isẹ ọfiisi rẹ le adari eto iṣẹ lọwọ, ti yoo maa ṣakoso ọfiisi alaga igbimọ ki wọn fi pari iwadi ti wọn fẹ ṣe,” o sọ siwaju.
Leave a Reply