Àdári Ìjọba tẹ́lẹ̀ rí tí Ìlú Gẹ̀ẹ́sì Boris Johnson f’ìwé mí ó ṣé mọ́ ránṣẹ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin ní ọjọ́ Ẹtì látàrí ìwádìí àwọn aṣòfin lórí rẹ̀.
Johnson tí wà lábẹ́ ìwádìí àwọn aṣòfin nípasẹ̀ bóyá Ó dárí Ilé-ìgbìmọ̀ Aṣòfin”House of Commons” dáradára nípa ajọyọ tó wáyé ni Downing Street lásìkò Covid-19.
Johnson, tí ìbínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ àti àwọn aráàlú gé ìṣèjọba rẹ̀ kúrú látàrí lílu òfin Covid-19 sọ́ pé, ìgbìmọ̀ náà kó ríi “ẹ̀rí kàn báyìí.” Ó ṣàlàyé pé ìwádìí òún kó yẹ̀ lọ́nà láti gbẹ́sán tí Brexit àtí látí dójú àbájáde náà bólẹ̀.
Igbimọ tó ń ṣé ìwádìí náà ní agbára látí fún Johnson ní ìwé gbélé ẹ́ ní ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin. Ṣùgbọ́n tí ìdádúró náà bá kọjá ọjọ́ mẹ́wàá, àwọn olúdìbò ní àgbègbè rẹ̀ lé bèèrè fún àtúndi ìdìbò láti tẹ̀síwájú gẹ́gẹ́ bí aṣojú wọ́n.
Ìgbìmọ̀ náà sọ pé yóò pàdé ní ọjọ́ Ajé láti dáhùn àwọn ìbéèrè rẹ̀ àti pé yóò fí àbọ̀ ìwádìí rẹ̀ hàn gbogbo ayé
Leave a Reply