Àwọn Àrìnrìn-Àjò Ọmọ Orílẹ̀-èdè Gẹ̀ẹ́sì Mẹ́ta Tí Sọnù Lẹyìn Tí Iná Jó Ọkọ Ojú-Omí Egypt
Ọlálékan Ọ̀rẹ́núgà
Àwọn àrìnrìn-àjò mẹ́ta ọmọ orílẹ̀-èdè Gẹ̀ẹ́sì United Kingdom tí sọnù lẹyìn tí ọkọ ojú-omí kékeré kán tí mú iná ní ọjọ́ Àìkú ní etí òkun Púpá ti Egypt.
Àwọn aláṣẹ sọ pé ènìyàn mẹ́rindìnlọ́gbọ́n mìíràn, pẹ̀lú àwọn ọmọ Britani méjìlá 12, ní a gbàla kúrò nínú ọkọ ojú-omí tí a pé ní ‘Hurricane,” èyítí o wà ní eti òkun tí Marsa Alam.
Wọ́n fí kún pé àwọn ìyókù ni wọ́n gbàla ní ibí ìsinmi eti omí tó wà nítòsí tí Marsa Shagra, bí kilomita mẹ́tàlà (21km) àríwá tí ìlú Marsa Alam, pẹ̀lú àwọn atukọ méjìlá ọmọ orílẹ̀-èdè Egypt àtí àwọn olutọsọna.
Àwọn aláṣẹ fí kún pé àwọn oníròyìn àkọ́kọ́ daba pé iná náà bẹ̀rẹ̀ ní àgó 06:30, ṣẹ̀lẹ̀ látàrí waya tó kàn àrà wọ́n.
Òkun Púpá jẹ́ ìbí ìsinmi tó gbajumọ fún àwọn àrìnrìn-àjò omí.
Ilé-iṣẹ́ ilẹ̀ òkèèrè tí Ìlú Gẹ̀ẹ́sì sọ pé o wà pẹ̀lú àwọn aláṣẹ àgbègbè nípa iṣẹlẹ náà àti àtìlẹ́yìn àwọn ọmọ ìlú tó kàn.
Leave a Reply