Ìbáṣepọ̀ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Àti Orílè-èdè China Lórí Ètò Ọjà Àtí Ọ̀rọ̀ Àjé Yóò Tú Bọ́ Gòkè Sí
Ọlálékan Ọ̀rẹ́núgà
Ìjọba Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ṣètò láti mú kí ìbáṣepọ̀ lórí ìṣòwò àti àwọn ìbátan ọ̀rọ̀-àjé gbòòrò sí pẹ̀lú Orílẹ̀-èdè China fún ànfààní àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì.
Èyí ní èrò láti mú kí ìwọn ìṣòwò láàrín Nàìjíríà àti China kún sí, kúrò lórí bílíọ̀nù méjìlá lé díẹ̀ dọla owó ilẹ̀ America ($12.03b) ni 2021.
Akọ̀wé àgbà ilé iṣẹ́, òwò àti ìdókòwò lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Dókítà Evelyn Ngige ló sọ èyí nílùú Abuja nígbà tí ìgbákejì olùdarí àgbà fún ẹ̀ka ọ̀rọ̀ ìṣòwò, Ẹ̀ka ọ̀rọ̀ òwò ti orílẹ̀-èdè China, Ọ̀gbẹ́ni Zhang Guanbin ṣé àbẹwò sí ilé iṣẹ́ náà.
Ìgbákejì Olùdarí Gbogbogbò, Ẹ̀kà Ìṣòwò, Ilé-iṣẹ́ Ìṣòwò tí Orílẹ̀-èdè China àti Olùdarí aṣojú, Ọ̀gbẹ́ni Zhang Guanbin gbóríyìn fún Ìjọba Àpapọ̀ Nàìjíríà fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tí wọ́n ń pẹ̀lú China lórí Ìṣòwò.
Tún kà nípa:Orílẹ̀-èdè America Ṣé Ìlérí Ìbáṣepọ̀ Rẹ̀ Pẹ̀lú Ìjọ̀ba Túntún Tí Ń Wọlé Bọ̀ Ní Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà
O tún sọ pé àwọn oludokowo Ìlú China ní Nàìjíríà gbàgbọ́ nínu ètò ìṣòwò tí Nàìjíríà, wọ́n sì fẹ́ kí owó ìṣòwò wọ́n pọ̀ sí ní Nigeria.
Nítorí náà, ó fi ìkésíni sí ìjọba Nàìjíríà fún kíkópa nínú Àpérò Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Àgbáyé ní China tí yóò wáyé ní October 2023.
Leave a Reply