Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ dákun Ìnira Yìí Pọ̀, Ẹ Báwa Wà Ǹkan Ṣe: Àwọn Ọmọ orílẹ̀-èdè Moroccans.

0 246

Ogunlọ́gọ̀ àwọn ènìyàn ló tú síta lati fi ẹdun inú wọn hàn ni agbègbè Casablanca ni Morocco látàrí nkan tó gbówólórí báyìí, ti ìjọba o sí ṣe àtúnṣe lásìkò.

Ìwọ́de eyi to wáyé pẹ̀lú àlàáfíà láti ọwọ́ àwọn ajìjàgbara fún àwọn òṣìṣẹ́ kakiri agbègbè náà.

Orílẹ̀-èdè Morocco ń kojú ìgbówólórí ọjà pàápàá jùlọ oúnjẹ èyí tó n ṣe àkóbá fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé báyìí.

Nínú osù kẹrin ní àwọn ìgbìmọ̀ ìjọba bá àwọn ajìjàgbara fún àwọn òṣìṣẹ́ se ìpàdé wí pé àwọn yóò fi kú owó oṣù wọn, ko bá jẹ alàádáni tàbí tí ìjọba.

Agbẹnusọ fún ìjọba Orílẹ̀-èdè náà ni àwọn ń gbìyànjú láti mú ìlérí àwọn ṣe bó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ètò ọ̀rọ̀ ajé o lọ síwájú tó.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button