Take a fresh look at your lifestyle.

Karim Benzema fi Real Madrid sílẹ̀ lẹ́yìn ọdún mẹ́rìnlá

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

1 256

Lẹ́yìn ọdún mẹ́rìnlá ní Real Madrid, Agbàmì ẹ̀yẹ Ballon d’Or Karim Benzema, yóò fi ilé-iṣẹ́ agbábọ́ọ̀lù  Spain sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olómìnira níparí sáà yìí, ilé iṣẹ́ agbábọ́ọ̀lù  LaLiga kéde ní ọjọ́ Àìkú, tí agbábọ́ọ̀lù náà sì ń lọsí ilé-iṣé agbábọ́ọ̀lù  Al Ittihad, ní Saudi Arabia.

Benzema, ọmọ ọdún márùndín-lógójì, darapọ̀ mọ́ Real Madrid ní ọdún 2009 lati  Olympique Lyonnais. Ọmọ Faransé náà di alátakò kan ṣoso fún iĺe  iṣẹ́ agbábọ́ọ́lù náà àti ẹni pàtàkì tí ó ń ju bọ́ọ̀lù sáwọ̀n, nígbà tí Cristiano Ronaldo lọ sí Juventus ní ọdún 2018. Benzema ju bọ́ọ́lù tó ju ọ́ta-dín-lẹ́ẹ́wàá- lélọ́ọ̀dúnrún lọ sáwọ̀n nígbà tí ó wà ní Real Madrid, tí ó sì jẹ́ ẹni tó ṣepò kejì nínú jíju bọ́ọ́lù sáwọ̀n nígbogbo ìgbà lẹ́yìn  Ronaldo.

Ìròyin sọ pé ọmọ Faransé náà ti ṣe àdéhùn ọlọ́dún méjì pẹ̀lú Al Ittihad. Benzema fẹ́ dúró si Real fún ọdún kan si ,ṣùgbọ́n ó tún ro ọjọ́ iwájú. Ó fojú fo ìfàsíwájú àdéhùn ọdún kan  rẹ̀ pẹ̀lú Real Madrid ,tí ó sì sọ pé òun ti ní láti gbé ìgbésẹ̀ fún ọjọ́ iwájú òun”.

One response to “Karim Benzema fi Real Madrid sílẹ̀ lẹ́yìn ọdún mẹ́rìnlá”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button