Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó gbàlejò gbajúgbajà agbábọ́ọ̀lù Arsenal, Bukayọ Saka
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó Babajide Sanwo-Olu gbálejò Agbábọ́ọ̀lù káríayé England, tí ó tún jẹ́ gbajúgbajà agbábọ́ọ̀lu Arsenal, Bukayọ Saka,ní ọjọ́ Abámẹ́ta,ní ọfiisi ilé-ìjọba, ní Marina.
Saka jẹ́ ọ̀kan lára ẹgbẹ́ Arsenal tí ó kujó Manchester City fún àmi ẹ̀yẹ Premier League, ṣùgbọ́n tí wọ́n fìdí rẹmi nígbẹ̀yìn sáà náà. Gómìnà Sanwo-Olu sọ pé ìjà fitafita Saka àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ jẹ́ ìwúrí fún ọ̀pọ̀lọpọ̀, tí èyí ṣì ń ṣàfihàn pàtàkì agbára àwọn ọ̀dọ́ nínú bọ́ọ̀lù gbígbá lágbàáyé.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn jákèjádò Nàìjíríà ló ń sọ̀rọ̀ nípa Gbajúgbajà agbábọ́ọ̀lù Arsenal láti ìgbà tó ti gúnlẹ̀ sí ìlú Eko láti ibùgbé rẹ̀, England.
Sanwo-Olu wá ṣàfihàn ìpinnu rẹ̀ láti lọ́wọ́ sí bọ́ọ́lù gbígbá ìgbèríko ní ìpínlẹ̀ náà.
Gómìnà wá sọ pé òun yóò lo bí Saka àti àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ ṣe mókè nítorí àfọkànsí àti ìpinnu wọn, láti ṣe ìtọ́jú ẹ̀bùn àwọn agbábọ́ọ̀lu kékèèké ní Eko, tí òun yóò sì fún wọn ní àǹfààní láti ṣàfihàn ara wọn.