Alága NGF kí adarí ilé ìgbìmọ̀ aṣojú Gbajabiamila, Akume kú oríire yíyàn wọ́n
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara, tí ó tún jẹ́ alága ẹgbé àwọn Gómìnà (NGF), AbdulRahman AbdulRazaq ti kí adarí ilé ìgbìmọ̀ aṣojú ki, Fẹmi Gbajabiamila àti Gómìnà tẹ́lẹ̀ rí, George Akume kú oríire yíyàn wọ́n bí ọ̀gá àgbà fún àwọn òṣìṣẹ́ ààrẹ (CoS) àti Akọ̀wé fún ìjọba àpapọ̀ ní sísẹ̀ntẹ̀lé.
Nínú àtèjáde kan tí ó fi síta ní ọjọ́ Àìkú, Gómìnà sọ pé àwọn arákùnrin méjééjì seé tọ́ka sí fún ipò tuntun wọn, pẹ̀lú àwọn ìrírí wọn gẹ́gẹ́ bí aṣòfin tó tá wọ́n yọ, adarí, àti ẹni tí ó ní ìfẹ́ orílẹ̀-èdè rẹ̀, tí ó sì kúnjú òsùnwọ̀n nínú àwọn iṣẹ́ tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn.
AbdulRazaq sọ pé òun ń retí àti ṣiṣẹ́ lálàáfíà pẹ̀lú àwọn adarí méjèèjì nípasẹ̀ ojúṣe òun bí Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara àti alága NGF.
Leave a Reply