Ẹgbẹ́ àwọn òsìṣẹ́ ojú omi ní Orilẹ-ede Naijiria ti parí ètò lati gùnlé ìyanṣẹ́lódì ní ọjọ Ajé látàrí ìgbé ayé tí ó kù díẹ̀ kààtó fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àjọ náà.
Alága àpapọ̀ ẹgbẹ́ náà, Adewale Adeyanju sàlàyé nígbà tí o n bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní ìlú Èkò wípé, ẹgbẹ́ náà ti gbáradì fún ìyanṣẹ́lódì látàrí bí àwọn alákòsóo ètò ọkọ̀ ojú omi se kùnà láti se àmójútó ti o péye fun ìgbáyégbádùn àwọn ọmọ ẹgbẹ naa.
Gẹ́gẹ́ bi Adeyanju se sọ, awọn alákòsóo ètò ọkọ̀ ojú omi kùnà láti fi ọwọ sowọpọ pẹlu awọn olóyè ẹgbẹ naa lojuna àti ni àsọyépọ̀ nipa ìgbáyégbádùn àwọn òsìṣẹ́ àjọ náà.
Leave a Reply