Take a fresh look at your lifestyle.

China Ṣetán Látí Ṣé Àtìlẹ́yìn Àlà Àwọn Ọ̀dọ̀ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà

Ọlálékan Ọ̀rẹ́núgà

0 286

Olùdarí tí Ilé-iṣẹ́ Àṣà Orílẹ̀-èdè China ní Abuja, Ọ̀gbẹ́ni Li Xuda, sọ pé Ìjọba Orílẹ̀-èdè China tí ṣetán láti ṣé àtìlẹ́yìn àwọn àlà àtí ìrètí àwọn ọmọ Áfríkà, pàápàá fún ọjọ́ iwájú àwọn ọ̀dọ̀ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Li sọ èyí dì mímọ̀ níbí ìdíje àyáwòrán “My dream” àtí ayẹ̀yẹ̀ ẹbùn fún àwọn ọmọ ilé-ìwé gíga ní Olú-ìlú Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Abuja.

Li yìn olúbóri ìdíje náà Ọ̀gbẹ́ni Prosper Daniel, ẹnití o gbá ẹbùn ipò kìíní nínú Ìdíje náà láàrín àwọn ẹgbẹ̀rún méjì 2,000 àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ nílẹ̀ Áfíríkà tá fí ránṣẹ sí Orílẹ̀-èdè China ní Oṣù Kẹta.

Li sọ pé Prosper Daniel yóò gbá ipé látí ṣàbẹwò sí Orílẹ̀-èdè China ní Oṣù Kẹsán tí ìjọba China yóò ṣé kókárí rẹ̀.

Tún kà nípa: Orìlẹ̀-èdè China Yóò Dènà Gbígbé Àgbá Wọlé Láti Agbègbè Tiwan.

Olùdarí Àgbà, National Council for Arts and Culture (NCAC) Otunba Segun Runsewe, gbóríyìn fún Ilé-iṣẹ́ ọmọ Ìlú China pẹ̀lú àwọn ètò alailẹgbẹ fún àwọn ọ̀dọ̀ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button