Ìjọba ìpínlẹ̀ Anambra ti fi ọwọ́ si iwe àdéhùn pẹlu ijọba àpapọ̀ lati ọwọ́ Ẹka Òṣìṣẹ́ àti Ìgbaniṣíṣẹ́ lati mu alekun ba iṣẹ ọwọ́ ni kíkọ́ ní ìpínlẹ̀ Anambra.
Gomina Chukwuma Soludo, ẹni ti Kọmísánnà Ìdàgbàsókè àwọn Ọ̀dọ, Patrick Agha soju fun pẹlu Minisita Osiṣẹ ati Igbanisiṣẹ tí ó sojú fún ìjọba àpapọ̀ dìjọ buwọ́ lu ìwé àdéhùn náà.
Wọ́n buwọ́lu ìwé àdéhùn náà ní ọ́ọ́fìsì Mínísítà àwọn Òsìṣẹ́ ní ìlú Abuja.
Ìrètí wà pé ìfọwọ́sowọ́pọ̀ naa yóò pese iṣẹ lọ́pọ̀ yanturu fun awọn ọ̀dọ́, yoo si mu alaafia jọba ní ìpínlẹ̀ náà.
Leave a Reply