Take a fresh look at your lifestyle.

Orílẹ̀-èdè Gẹẹsi Ní Orílẹ̀-èdè Àkọkọ́ Látí Pèsè Òun Ìjà Olóró Ọlọna Gigun Fún Orílẹ̀-èdè Ukraine

Ọlálékan Ọ̀rẹ́núgà

0 306

Orílẹ̀-èdè Gẹ́ẹ̀sì ní Ọjọ́bọ̀ dì orílẹ̀-èdè àkọkọ́ látí bẹ̀rẹ̀ sí pèsè fún Ukraine pẹ̀lú àwọn misaili òun ìjà ọlọna gígùn, èyítí yóò ràn àwọn ọmọ ogún Ukraine lọwọ́ látí kojú àwọn ọmọ ogún Russia.

Ukraine tí n béèrè fún àwọn òun ìjà misaili gígùn tí pẹ́, ṣùgbọ́n tí àwọn àlàtìlẹ́yìn bìí Orílẹ̀-èdè Gẹẹsi àtí àwọn ọrẹ mìíràn bìí Amẹrica kọ̀ látì pèsè rẹ̀.

Mínísítà Ààbò Ìlú Gẹẹsi, Ben Wallace sọ fún ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin pé: “Russia gbọdọ mọ pé àwọn iṣe rẹ̀ nìkàn tí yọrí sí irú àwọn ètò tí a pèsè.”

Tún kà nípa: Pàsípàrọ̀ Àyájọ́ Àjíǹde: Orílẹ̀-èdè Ukraine Rí Ẹrú Ogun Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà Gbà Padà

Wallace sọ pé Ìlú Gẹẹsi ń pèsè àwọn misaili wọnyí sí Ukraine kí wọ́n lè ṣéé ìdáàbòbò fún àgbègbè rẹ̀, tó túmọ̀sí pé o tí gbà àwọn ìdánilójú látí Ukraine pé wọ́n kíì yóò ló látí kọlù Ilẹ̀ Russia kọọkan.

Ó tèsíwájú pé, àwọn òun ìjà náà “ ló tí ń lọ́ sí, tàbí wà nínú orílẹ̀-èdè Ukraine.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button