Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Buhari Ṣí Àwọn Ìṣẹ́ Àkànṣe TETFUND Ẹlẹgbẹ-gbẹ́ Bílíọ̀nù Náírà Ní Makurdi

Ọlálékan Ọ̀rẹ́núgà

0 321

Ààrẹ Muhammadu Buhari ní Ọjọ́bọ̀, tí ṣí àwọn iṣẹ́ àkànṣe mẹ́fà nípasẹ̀ Àjọ ìnáwó Ilé-ẹ̀kọ́ gíga (Tertiary Education Trust Fund TETFUND) ní ilé-ìwé gíga tí Benue State University, Makurdi, ní Àárín gbùngbùn Àríwá, Nàìjíríà.

Ààrẹ Buhari tí Sẹnetọ George Akume Mínísítà Ìṣẹ́ Àkànṣe àtí Ìjíròrò láàrín àwọn Ìjọba ṣé aṣojú rẹ̀, ṣé àkíyèsí pé pẹ̀lú àtìlẹ́yìn ìjọba àpapọ̀, TETFUND tí ṣiṣẹ́ takuntakun lórí ilé kíkọ́, àtìlẹ́yìn fún ikẹkọ ati ìdàgbàsókè àwọn òṣìṣẹ́,ìwé títẹ jáde, ICT, àtí Ìwádìí àti Ìdàgbàsókè ní àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga tí gbogbo ní orílẹ̀-èdè yìí.

Tún kà nípa: Ààrẹ Buhari Fọwọ́sí owó tó tó bílìọ̀nù mẹ́rin ó lé díẹ̀ Fún Iṣẹ́ Ìwádìí Tetfund

Ó tọka sí wípé yàtọ sí Ilé-ẹ̀kọ́ gíga tí Ìpínlẹ̀ Benue, Makurdi, àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga mẹjọ mìíràn bíi Joseph Sarwuan Tarka, Makurdi, tún jẹ́ ànfààní yìí.

Ààrẹ Buhari rọ àwọn tó ń jàǹfààní nínú àwọn iṣẹ́ náà tí iye rẹ̀ lé ní bílíọ̀nù méjì àti mẹ́fà náírà láti dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ ìbàjẹ́.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button