Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun tẹ́lẹ̀, Adegboyega Oyetola ti faramọ́ ìdájọ́ ilé-ẹjọ́ tó ga jù,tí ó gba ìbò Sẹ́nétọ̀ Ademola Adeleke wọlé gẹ́gẹ́ bíi gómínà ìpínlẹ̀ náà.
Oyetola nínú àlàyé kan tí òun fúnra rẹ̀ buwọ́lù,sọ pé ìdájọ́ ilé-ẹjọ́ náà kò dùn mọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àti àwọn olólùfẹ́ ẹgbẹ́ nínú ,ṣùgbọ́n òun gbàá bẹ́ẹ̀ kí àlààfíà lè jọba ati kí ìdàgbàsókè lè wáyé ní ìpínlẹ̀ náà.
Gómìnà tẹ́lẹ̀ náà wá rọ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀,All Progressives Congress, APC, àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ àti àwọn tó dìbò fun lásìkò ìbò gómìnà,lọ́jọ́ kẹrìndín-lógún,oṣù Agẹmọn, 2022 láti gba ìdájọ́ náà gẹ́gẹ́ bí ọlọ́run ṣe kọọ́,kí àwọn si gbàgbé nípa rẹ̀.
Leave a Reply