Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé Ẹjọ́ Faranse Kan Dá Àwópalẹ̀ Ibùgbé Ibi Ìdọ̀tí Dúró

0 218

 

Ilé ẹjọ́ Faranse kan ti dá àwópalẹ̀ ibùgbé ibi ìdòtí tí ó wà ní Indian Ocean island, agbègbè Mayotte tó jẹ́ ilé fún àwọn tó n lọ sí orílẹ̀-èdè míràn káàkiri ni ọ̀nà àìtọ́ dúró.

 

Ìròyìn ró pé ọ̀kan lára agbègbè erékùṣù Faransé náà ti di ibùgbé fún àwọn tó n lọ sí orílẹ̀-èdè míràn káàkiri ni ọ̀nà àìtọ́ pàápàá jù alámúlétì wọn Comoros.

 

Agbófinró bí ẹgbẹ̀rún méjì ni wọ́n ti fi sí agbègbè Mayotte láti má ṣe iṣẹ́ wọn ni agbègbè náà tó sì ti fa ọ̀pọ̀ ìkọlù ní ìlú nlá bí Mamoudzou.

 

Síbẹ̀síbẹ̀, Olùdarí ìjọba ìbílẹ̀ ti sọ pé àwọn yóò pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn fún ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ dá.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button