Ààrẹ orílẹ̀-èdè yii, Muhammadu Buhari ti sọ pé Ìjọba Àwarawa yóò di igi àlọ́yè. Ó fi kun pé bí òun se ń fi ipò sílẹ̀ láìpé, inú òun dùn, ó sì dà òun lójú pé iná ìjọba àwarawa tó ti ń jó àlọsíwájú kòní jó àjó rẹ̀yìn.
Nígbà ti ó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ kété lẹ́yìn ádúrà ọdún ìtùnú ààwẹ̀, ó sọ pé:
“Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè yìí mọ ìdúró ṣinṣin ìjọba àwarawa. Èsì ìbò tó kojá ti Gómìnà tó ju mẹ́wàá kò leè yege sí ipò Sénétọ̀ fi yé wa pé àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè yìí mọ ìtumọ̀ agbára ìbò wọn àti bí wọn se lè ló.
“Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè yìí féràn ìjọba àwarawa.Wọ́n ti fi ìfẹ́ wọn hàn síi, wọ́n ó sì dáàbòbó.”
Ààrẹ jẹ́ kó di mímọ̀ pé ọjọ́ gbígbé ìjọba kalẹ̀, ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù karùn ún sì wà bẹ́ẹ̀.
” Ní ọlá Ọlọ́run, nǹkan kan kò ní yẹ́,” ó fi kún un.
Èròngbà ààrẹ ní kété tó bá fi ipò sílẹ̀ ni kí ó padà láti Àbújá lọ sí ìlú rẹ̀, kí ó ta kété sí ààrẹ tuntun láti rí ààyè gbájúmọ́ iṣẹ́ rẹ̀.
” Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún nǹkan tó ti lò mí àti gbogbo wa láti lè ṣe.
Mo ń padà lọ sí ìlú mi kí ààrẹ tuntun leè ni àkókò àti ààyè láti se ìpinnu àti láti lè ṣe iṣẹ́ rẹ̀ láì di lọ́wọ́,” ó fi kún un.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply