Take a fresh look at your lifestyle.

Ìkéde Ìgbanisísẹ́, Ìròyìn Òfegè Ni – Àjọ Ọmọ Ogun Ojú Omi Kìlọ Fún Àwọn Ọmọ Orílẹ̀-èdè Yí

0 201

 

Àjọ Omo Ogun Ojú Omi Orílẹ̀-èdè yí ti pariwo sí ìta látàrí ìròyìn Irọ́ tó ń lọ lórí ẹ̀rọ ayélujára nípa ètò Ìgbanisísẹ́ ti ọdún 2023.

 

Ọ̀gá àgbà ti ètò ìròyìn ilé iṣẹ ọmọ ogun ojú omi, Commodore Adedotun Ayo- Vaughan sọ pé àwọn òbàyéjẹ́ náà tilẹ̀ tún ni kí àwọn ènìyàn mú àdírẹ́sì àti nọ́ḿbà ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ àwọn onígbọ̀wọ́ mẹ́ta wọn wá, ó sọ pé àjọ ọmọ ogun ojú omi orílè-èdè yìí kò gbé nǹkan tó jọ bẹ́ẹ̀ sí ita, ìròyìn òfegè ni.

 

Bí ó se sọ, ó jẹ́ ọ̀nà láti si àwọn ènìyàn ni ọ̀nà àti láti ja àwọn ènìyàn tí kò mọ ọwọ́ mọ ẹsẹ̀ lólè ni.
“Látàrí èyí, kí àwọn ènìyàn sö ara wọn, kí wọ́n máa bàá já wọ́n ní olè láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn arúfin burúkú yìí tó wà lẹ́yìn isẹ́ ibi náà”.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button