Take a fresh look at your lifestyle.

Àjọ INEC Gbé Èsì Ìbò Àtúndì Jáde Ní Ìpínlẹ̀ Bayelsa

0 314

 

Àjọ Independent National Electoral Commission (INEC) ti kéde ní ọjọ́ Àìkú, ọ̀gbẹ́ni Rodney Ambaiowe ti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP gẹ́gẹ́ bí ẹni tó já ewé Olúborí ìbò àpapọ̀ ẹ̀ka ti Gúsù – Ijaw ní Ìpínlẹ̀ Bayelsa.

 

Bí olùkéde ìbò, ọ̀jọ̀gbọ́n Christopher Onyema, se kéde, ọmọ ẹgbẹ́ PDP, Ambaiowei ní àpapọ̀ ìbò 13,992 tó fi borí alátakò rẹ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Preye Oseke tí òun náà ni 12,992 ìbò.

 

Bákannáà, àjọ INEC ti kéde ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Godknows Obein, bí ẹni tí ó jáwé olúborí ní ìbò ilé aṣòfin ti Ìpínlẹ̀ Bayelsa, Ogbia Constituency 2.

 

Bí olùkéde ìbò, ọ̀jọ̀gbọ́n Johnson Ohakwe se kéde, ọ̀gbẹ́ni Obein ní ìbò 5,291 láti fi la ọ̀gbẹ́ni Munalayefa Gibson ti ẹgbẹ́ PDP, ti òun náà ní 4,342 ìbò.

 

Pẹ̀lú èsì ìbò yìí, ẹgbẹ́ PDP yóò ní ìjòkó mẹtàdínlógún, Ẹgbẹ́ APC yóò ní márùn ún àti ẹgbẹ́ Progressives Grand Alliance (APGA) yóò ní méjì péré ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ẹlẹ́ẹ̀keje ti ìpínlẹ̀ Bayelsa.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button