Àjọ tí ó ń mójú tó lílọ-bíbọ̀ àti ìrìn àjò ojú omi ti se àgbékalẹ̀ ọkọ̀ ojú omi ìgbàlódé, lójúnà àti mú ìgbòòrò bá kárà-kátà àti fún wíwá ọ̀nà láti pawó wọlé fún ìjọba.
Ọ̀gá àgbà àjọ NIMASA, Basir Jimọh ni ó sọ ọ̀rọ̀ náà ní ọjọ́ Ìsẹ́gun, Ó sì fi èrò-ń-gbà àjọ náà láti kópa nínú òwò kálọ-kábọ ọkọ̀ ojú omi hàn. Ó sàlàyé pé ó wà lára ọ̀nà láti mú ojúse àjọ náà wá sí ìmúsẹ.
Gẹ́gẹ́ bí Jimọh se sọ, àjọ náà ti ra ọkọ̀ ojú omi ńlá mẹ́rin, tí ìrètí sì wà pé kí osù kẹrin ọdún 2023 tó parí, àwọn ọkọ̀ náà yóò ti wà ní ìkáwọ́ àjọ náà, léyìí tí Mínísítà tí ó wà fún ìgbòkè-gbodò ọkọ̀, Muazu I. sambo yóò se ìfilọ́lẹ̀ lílò àwọn ọkọ̀ náà.
Leave a Reply