Take a fresh look at your lifestyle.

Ethiopia: Ẹgbẹgbẹ̀rún Ènìyàn Lọ Síbi Àpèjẹ Oúnjẹ Àṣálẹ́ Ní Addis Ababa

0 234

 

Ẹgbẹgbẹ̀rún àwọn ẹlẹ́ṣìn Mùsùlùmí láti ìletò kan ni orílẹ̀-èdè Ethiopia kópa níbi àjọ nla àdúgbò ‘iftar’, ìtùnú ààwẹ̀ ti Ramadan ní Meskel Square ní ìlú Addis Ababa, láti fi ṣe ìkówójọ fún àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè tí wọ́n fán káàkiri nípasẹ̀ àìní.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Mílíọ̀nù àwọn ènìyàn ní orílẹ̀-èdè Ethiopia ni wọ́n ti fán káàkiri látàrí rògbòdìyàn àti ọ̀dá omi.

Àwọn adarí láti ọ̀dọ̀ ìgbìmọ̀ Islamic Supreme ti orílẹ̀-èdè Ethiopia ló pésẹ̀ síbẹ̀, wọ́n sì rọ àwọn Mùsùlùmí láti má tẹ̀síwájú nípa oore sise títí àti lẹ́yin Ramadan.

Orílẹ̀-èdè Ethiopia jẹ́ orílẹ̀-èdè tí ìdákan nínú mẹ́ta rẹ̀ jẹ́ ti ẹlẹ́ṣìn Mùsùlùmí, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ yókù jẹ́ ti ẹlẹ́ṣìn ìgbàgbọ́. Ìjà ẹ̀ṣìn sì ti dá rúgúdù sílẹ̀ ní àárín wọn ní ìgbà kan rí.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button