Gbajúgbajà olùdánilárayá David Adeleke tí gbogbo ayé mọ̀ sí Davido, ti se ìfiléde àwo orin mẹ́ta láti fi se ayẹyẹ àkójọpọ̀ orin rẹ̀ tí ó pè ní “Àìlópin” léyìí tí ó se ìkéde rẹ̀ ní kété tí ó padà sí orí ẹ̀rọ ayélujára. Ó sàlàyé pé òun yóò kọ orin náà ní United Kingdom, United States, àti Lagos ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Akọrin náà fi ọ̀rọ̀ náà léde ní Ọjọ́rú, ní orí ẹ̀rọ abẹ́yẹfò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìkéde àkọ́kọ́ lórí ẹ̀rọ ayélujára lẹ̀yìn ìgbà tí ó pàdánù ọmọdé kùnrin rẹ̀, Ifeayin.
Ìfiléde àwo orin tuntun náà mú kí inú àwọn olólùfẹ́ Davido dùn tí wọ́n sì setán láti lọ sí ibi ayẹyẹ náà, èyí tí ìrètí wà pé yóò wáyé ní ọjọ́kọkànlélọ́gbọ̀n osù kẹta.
Davido yóò seré ní United Kingdom, United States tí yóò sì padà sí ìlú Èkó ní Ọjọ́ kẹtàlélógún, osù kẹrin. Èyí tí ó pe àkọlé orin náà ní “Alẹ́ Àìlópin pẹ̀lú Davido”.
Leave a Reply