Ọ̀rọ̀ Ìdúpẹ́ Àti Ìdúpẹ́
Adari Ilé Igbimọ, Gbajabiamila dupẹ lọ́wọ́ gbogbo àwọn Oludibo Surulere 1 fún Oore-Ọfẹ Ẹlẹkẹfà ti wọn fún wọ́n, O ṣé Ìpínnù wí pé Òun kò ní já wọ́n kulẹ̀. Ati pe Òun yóò tún tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìṣẹ takun -takun tí ó ń ṣe láti mu ìdàgbàsókè ba Ẹkún Surulere.
Gbajabiamila sọ pé “Mo dupẹ gidigidi lọ́wọ́ Ẹyin Ènìyàn Surulere fún ìdúrótí Aláìlẹ́gbẹ yín. Mi o fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ìdúró tí yín.
“Gẹ́gẹ́ bi Aṣojú yín fun Ogun Ọdún le, ìdùnnú yín ní ayọ̀ mí. Mo ń fi yín yangàn gẹgẹ bi àgbègbè ti mo ti wà. Mo dupẹ pupọ lọwọ àwọn Alatilẹyin mí, àwọn èjìká tí ko jẹ kí aṣọ jabọ – Àgbààgbà ati Ẹ̀gbẹ Òṣèlú APC, CDAs ati awọn Olugbe Surulere fun atilẹyin yín tí o Tayọ.
“Àṣeyọrí ki ń ṣe ti témi nìkan ṣoṣo. Àṣeyọrí Òṣèlú ni. Surulere ti kọ ìwé itan fún Àṣeyọrí Ẹlẹkẹfà ti ẹ fún mi yìí, ti yóò si fún mi ìwúrí láti ṣe jù bí mo ti n ṣe tẹlẹ lọ.”
A yàn Ádárì Ilé igbimọ Aṣojú Ṣòfìn ni akọkọ ni Ọdún 2003 gẹ́gẹ́ bí Aṣojú Surulere 1 ti Ẹkún Ìjọba Apapọ láti ìgbà náà ni ó tì ń jáwe Olubori. Ó jẹ́ ẹnì akọkọ tí ó ní ànfààní yìí fún ìgbà mẹ́fà gbáko
Ó ti jẹ àwọn oyè wọ̀nyí nínú ìrìnàjò ogun Ọdún rẹ:
Olórí Agbófinró Alátakò ni gbọngan Ìjọba Apapọ, Olori Àwọn Ọmọ Ẹ̀gbẹ Alátakò ati Olori Ẹ̀gbẹ Àwọn Òṣèlú Abẹnugọ. Ki o to wa di Ádárì Ilé igbimọ Aṣojú Ṣòfìn ni Ọdún 2019. O jẹ Aṣòfìn akọkọ ní Ilẹ̀ Adúláwọ tí ó kọ́kọ́ jẹ́ irú àǹfààní yìí.
Leave a Reply