Ìdìbò Tẹ̀síwájú Lónìí, Ọjọ́ Kerìndínlọ́gbọ̀n, Oṣù Kejì Ní àwọn agbègbè kọ̀ọ̀kan ní Ìpínlẹ̀ Edo
Ìdìbò yóò tẹ̀síwájú Lónìí ọjọ́ àìkú, ọjọ́ kerìndínlọ́gbọ̀n oṣù kejì, ọdún 2023 ni àwọn agbegbe kọọkan ni ìpínlẹ̀ Edo, ẹkun gúsù orílẹ̀-èdè Nàíjíríà.
Ìdìbò yìí yóò wáyé lati dédé ago mẹjọ àárọ̀ sí aago mejila ọ̀sán ní àwọn agbegbe Etsako, ẹkun ìwọ̀-oòrùn, Etsako ẹkun ìlà-oòrùn àti àwọn agbegbe mííràn tí wọn ò dárúkọ
Àjọ elétò ìdìbò ló tọ́ka sí pé àwọn agbègbè yìí tí ìdìbò ò wáyé ní ọjọ́ Sátidé àná, Oṣù kejìlá ọjọ́ karundinlọgbọn ni wọ́n sún sí ọ̀ní ọjọ́ kerìndínlọ́gbọ̀n oṣù kejì, ọdún 2023.
Ọláyinká Akíntọ́lá.
Leave a Reply